Photo credit: the Telegraph
Orile ede Rwanda ti so wipe toro to yo, orile ede United Kingdom ko le rigba ninu owo to da awon orile ede mejeji po.Dokita Doris Picard ti owa ni ile ise ofin ijoba Rwanda so pe ilu Rwanda ti ko ipa tie.
Ijoba ana lori ile ede United Kingdom tin gbero lati ma fi oko ofurufu ko awon ti won gba ona eburu wo ilu na lo si Rwanda. Nidi eyi, won ti fun ijoba Rwanda ni orinlenigba o din mewa milionu owo poun lati fi se eto na.
Sugbon ijoba tuntun ti olori re nje Keir Starmer ti faake kori. Won ti da eto na nu bi omi isanwo.
Picard so wipe ijoba ilu oun o je ayo pa nitori awon ti se oun to ye ki awon se. Sugbon o s’eleri pe awon ijoba mejeji a si ma se apero lati igba de igba.Ko si adehun to kan nipa ki awon orile ede mejeji lati da owo pada. Ni bayi, ijoba ile United Kingdom o ti fun ijoba Rwanda ni iwe osu meta to ye ki won fi so wipe awon o se adehun odun marun na mo. Amo o, ninu iwe adehun, ijoba United Kingdom le da owo to to aadota milionu poun to ye ki won san fun odun 2025 ati 2026 duro lai san.
Dokita Picard bu enu ate lu ajo UNHCR ti on s’oju fun ajo UNITED Nations lori eto asala. UNHCR ti benu ate lu orile ede Rwanda tele wipe kii se ibi ti awon alasala le lo ni.